Back

Laarin ọjọ meeedogun ileeṣẹ aṣọbode Ogun gba ẹru ofin to le ni biliọnu mẹta naira lọwọ fayawọ.

Johnson Akinpẹlu.

Ileeṣe aṣọbode to wa ni Idiroko ti sọ pe laarin ọjọ mẹẹdogun lawọn fi ri ẹru ofin to le ni biliọnu mẹta naira gba lọwọ fayawọ.

Abdulhamid Ibrahim to jẹ adele ọga agba fun aṣọbode nipinlẹ Ogun lo sọrọ lakooko to n bawọn oniroyin sọrọ lori aṣeyọri wọn.

O sọ pe lara awọn nnkan ti wọn ri gba ni aloku aṣọ ṣoja, apo irẹsi, igbo, mọto mẹtala atawọn ẹru ofin yooku.

Ọga agba ọhun sọ pe latigba toun ti wọ iṣẹ gẹgẹ bi olori wọn lawọn ko ti foju awọn oniṣẹ ibi ọhun balẹ, eyi lo si ran wọn lọwọ tọwọ fi tẹ awọn nnkan wọnyii lakooko igbiyanju wọn la tii ko wọle.

O ṣalaye siwaju pe lọjọ keji, oṣu yii lọwọ awọn oṣiṣẹ oun kọkọ tẹ awọn onitirọọki mẹta ti wọn fẹẹ ko ayederu ounjẹ wọlu.

Bẹẹ lo sọ pe lọjọ kẹrin oṣu yii bakan naa lọwọ wọn tun tẹ tirela Dangote ti wọn apo baagi irẹsi tiyẹn to ọgọrun- un.

Lọjọ kọkanla oṣu yii lawọn tun gba tirela to kun fun aṣọ awọn ṣoja ati fila wọn atawọn ogun oloro pẹlu.

O wa tari awọn aṣeyọri ti wọn ṣe si ọga agba wọn pata, Bashir Adeniyi Adeawale nitori akitiyan ẹ lati jẹ ki fayawọ dinku lorileede yii.

The full article is being collected. Available text is shown for now.

Back
Share this story

Get the daily newsletter →

Ask globalread.info

AI news & website helper
What would you like to explore?

I can find stories, explain headlines, or help you use globalread.info.

AI can make mistakes. Check the linked sources. Questions are sent to OpenAI.